Àgẹ̀rẹ̀

Ìlù Àgẹ̀rẹ̀ jẹ́ ìlù àtijọ́, ìlù àtayébáyé. Nítorí ìró aminlẹ̀ tí ó ní, ìlù àgẹ̀rẹ̀ ni ìlù àwọn ògbójú ọdẹ àtijọ́. Bákannáà, wọ́n máa ńlù ìlù àgẹ̀rẹ̀ nígbàtí ọlóde tàbí onífa tàbí ọba ìlú bá pa ipò dà. Ní àfikún, wọ́n tún máa ńlu ìlù àgẹ̀rẹ̀ fún àwọn ọba àti ìjòyè láti yẹ́ wọn sí.

Ìlù àgẹ̀rẹ̀ àti ìlù àpèsìn jọ ara wọn. Àwọn ìdílé onílù kannáà ni ó máa ńlu ìlù méjèèjì. Wọ́n máa ńlu ìlù àpèsìn nígbàtí ó bá yẹ láti jó kiri pẹ̀lú ìlù. Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, ìjókǒ ni wọ́n ti máa ńlu ìlù àgẹ̀rẹ̀. Ìlù àgẹ̀rẹ̀ kò ní ọ̀já tí a le fi gbée kọ́ èjìká, ó sì leè wúwo pupọ̀.

Àwọn onílù àgẹ̀rẹ̀ àti àpèsìn jẹ́ onílù nítorí ìdílé tí a ti bí wọn. Èyí jásí wípé ìlù àgẹ̀rẹ̀ àti ìlù àpèsìn lúlù jẹ́ àti ìran de ìran. Ìdílé onílù àgẹ̀rẹ̀ àti àpèsìn rọ̀ mọ́ iṣẹ́ ‘ọdẹ’ àti iṣẹ́ ‘àgbẹ̀dẹ’ - rírọ irin sí ohun èèlò bíi ọkọ́, àdá, ọ̀bẹ ìfíngbá, ọ̀bẹ ìfágbá, páńpẹ́, àáké, àti bẹ́è bẹ́è lọ láti mú kí iṣẹ́ àgbẹ̀, iṣẹ́ ọdẹ àti igbá fínfín rọrùn.