Àjàyí gbọ́ ìtumọ̀ ìlù

Àjàyí lọ sí ibi ayẹyẹ ìwúyè ní ìlú Ayépé. Ní ibi ìwúyè, àwọn onílù fi ìlù dárà! Wọ́n fi ìlù ki oríkì, wọ́n fi ìlù pa òwe, wọ́n fi ìlù sọ àṣàyàn ọ̀rọ̀, wọ́n tún fi ìlù kọ orin. Kí á tó ka méní, méjì, Àyádìran kọ ojú ìlù sí Àjàyí, Àdùkẹ́ àti Àdùní. Àwọn ọmọdé bẹ̀rẹ̀ síí jó, gọngọ sọ!

Ìwé Àjàyí gbọ́ ìtumọ̀ ìlù jẹ́ ìwé tí a ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní fún àkàgbádùn àwọn ọmọdé pẹ̀lú àwọn òbí. Ìwé yǐ fi ìlò èdè àti ẹwà èdè Yorùbá bíi òwe, àṣàyàn ọ̀rọ̀, oríkì àti ìjìlẹ̀ ọ̀rọ̀ hàn. Bákannáà, ìwé yǐ tún fi àṣà àti ìṣe Yorùbá hàn ní ọ̀nà tí ó le rọrùn fún àwọn ọmọdé wa láti tẹ̀lé.