Àpèsìn

Ìlù àpesìn jẹ̀ ìlù àtijọ́, ìlù àtayébáyé. Wọ̀n máa ńlu ìlù yí fún àṣà ìbílẹ̀ nítorí ìró ìyàtọ̀ tí ó ní. Ìlù àpèsìn ni wọ́n máa ńlù sí orin gẹ̀lèdé.Ìlù àpèsìn àti ìlù àgẹ̀rẹ̀ wá láti inú ẹbí ìlù kannáà. Wọn máa ńlu ìlù àpèsìn ní’gbà tí àwọn onílù yǐ bá ní láti jó kiri. Báyǐ, onílù àpèsìn le gbé ìlu yí kọ́ èjìká pẹ̀lú ọ̀já rẹ̀ tí ó dàbíi ti dùdún. Ọwọ́ ni wọ́n fi ńlu ìlù àpèsìn, fún ìdí èyí, lúlu ìlù yí láti fi ki oríkì, pa òwe, sọ àṣàyàn ọ̀rọ̀ àti láti fi lu àlùjó gba ọgbọ́n àti àfi ojú-fi ọkàn yàn.

Àwọn ará Ìbàràpá àti Òkè-ógùn fẹ́ràn Ìlù àpèsìn àti ìlù àgẹ̀rẹ̀ púpọ̀.