Ògìdo

Ìlù tutun ni ògìdo jẹ́, kìí ṣe àtayébáyé bíi dùndún, bàtá, àpèsìn àti àgẹ̀rẹ̀. Ògìdo ní orúkọ míràn bíi ‘kóńgà’, ‘àkúbà’, tàbí ‘dùùrù’.

Ògìdo máa ńdún bíi àdàpọ̀ ìró láàrin dùndún àti àpèsìn. A le rí ìlù ògìdo nínú àkójọpọ̀ ìlù nínú orin òde òní. Ìró ògìdo rinlẹ̀, ó dùn yùgbà létí

Fún ìro tí ó rinlẹ̀ tí ògìdo ní, ìlù ògìdo ni ìlù tí àwọn ilé ìjọsìn Aládǔrà jákè-jádò ilẹ̀ Yorùbá yàn láàyò.

A kì í lu ilu ògìdo láti fi bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀.