Àjàyí


Àjàyí Ògídí olú. Ọmọ arówó seré nì ìdí àpè, ọmọ ò toko bọ̀ ṣe bíi ọba.

Àjàyí fẹ́ràn àwọn ẹbí rẹ̀, pàá-pàá jùlọ Ìyá àgbà fún ààlọ́ tí wọn máa ńpa nípa ìjàpá ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́.

Àjàyí fẹ́ràn àṣà àti ìṣe púpọ̀, pàá-pàá jùlọ nígbà tí ó bá wọ aṣọ òkè rẹ̀ tí a dá ní gbárìyẹ̀, ṣòkòtò àti fìlà tí ó gbámúṣé.

Àjàyi bá àwọn òbi rẹ̀ lọ sí ibi ìwúyè ní ìlú Ayépé, ní ibi tí ó ti pàdé àwọn ọmọ ẹ́gbọ́n ìyá rẹ̀, Àdùkẹ́ àti Àdùní. Àyándìran onílù àrà àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Aríjóyọ̀ sọ ìlù sí wọn ní’bàdí, oyin mọmo, oyin àdò ni!