Ilé ọgbọ́n. Ìyá àgbà,
Ọmọ òṣèré onílẹ̀ obì, ọmọ oníyán pupa, ọlọ́bẹ̀ pupa.
Ọmọ ẹlẹ́ní ẹwẹlẹ. Ọmọ atẹ́níwíjọ́ k'ọ́rọ̀ ó má baà jò sílẹ̀.
Ìyá àgbà ó gbẹ́yìn nínú àjọọṣepọ̀ láti kọ́ áwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀. Èròǹgbà wọn ni láti ríi wípé Àjàyi àti àwọn ọmọdé ìyókùn ńhu ìwà ọmọlúàbí.