Bàtá jẹ́ ìlù pàtàkì míràn tí a mọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá. A máa ńlu ìlù Bàtá fùn ijó àpilẹ̀jó. Ní ibi ijó àpilẹ̀jó, àwọn oníjó tí ẹ máa rí níbẹ̀ á jẹ́ àwọn tí ó mú ijó jíjó gẹ́gẹ́ bíi iṣẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé gbogbo ọmọ Yorùbá ni ó le gbé ẹsẹ̀ sí ìró ìlù Bàtá, ìgbẹ́sẹ̀ sí’lù Bàtá tí ó ní ìtumọ̀ sì wà pẹ̀lú àwọn tí ó mú ijó jíjó gẹ́gẹ́ bíi iṣẹ.
Ní ayé àtijọ́, a máa ńlo ìlù Bàtá láti ki àwọn ọba àti àwọn ìjòyè ìlú nì ojoojúmọ́. Lóde òní, ní àwọn ìlú kékeré, àwọn onílù Bàtá sí ńlu ìlù láti fi ki àwọn ọba áti ìjòyè wọn ní ọ̀sẹ̀-ọ̀sẹ̀. Fún ìró líle àti ìró akọ tí ìlù Bàtá ní, ìlù yǐ ni wọ́n máa ńlù fún ijó ṣàngó àti egúngún. A ńlo ìlù Bàtá lóde òní nínú àkójọ ìlù láti mú kí orin ilẹ̀ Yorùbá lóyin ládùn létí.
Alubàtá leè fi ìlù Bàtá ki oríkì ní ìbámu pẹ̀lú ilé tí a ti bí ẹnìkọ̀ọ̀kan. Bákannáà, alubàtá le fi ìlù Bàtá pa òwe tàbí fi sọ àṣàyàn ọ̀rọ̀ nínú ìlù àlùjó tàbí ìlù àlùgbọ́.
Bàtá lúlù àti jíjó sí ìlù Bàtá gba agbára díẹ̀. Bí alubàtá bá ti ńlu ìlù, bẹ́ẹ̀ni oníjó á máa tàpá, gbé ara sókè ní ìbámu pẹ̀lú ìró ìlù. A ò le jó Bàtá kí á má la òógùn. Abarapá ló le jó Bàtá, Bàtà kìí ṣe t’ọlọ́kùrùn. Bákannáà, bí oníjó bá ti ńla òógùn, ìró akọ ìlù yǐ máa mú kí àwọn olùgbọ́ náà ju ẹsẹ̀ ní ibi tí wọ́n wà. Alubàtá àti ajóbàtá máa ńṣiṣẹ́ papọ̀ ni. Ajóbàtá máa gbé ara ní ìbámun pẹ̀lú ìró akọ ìlu àti ohun tí ìlù ńsọ. Ìró akọ tí bàtá ní ló máa ńmú kí àwọn ajóbàtá jó lákọ-lákọ. Jíjó lákọ-lákọ sí ìró ìlù wà nínú ijó ìlù àgẹ̀rẹ̀ náà.
Àwọn alubàtá jẹ́ alubàtá nítorí ilé tí a ti bí wọn lọ́mọ. Èyí jásí wípé, Àyádèjì jẹ́ alubàtá nítorípé bàbá àti baba-baba rẹ̀ alubàtá ni wọ́n. Nínú ẹbi alubàtá, bíi àwọn ẹbí onílù ìyókùn, ẹ̀kọ́ ìlù lúlù bẹ̀rẹ̀ láti kékeré. Èyí máa mú kí àwọn ọmọ wọ̀nyǐ ní ìfẹ́ sí ìlù lúlù láti kékeré. Gẹ́gẹ́ bí òwe Yorùbá se sọ wípé, ọmọ tí yóò jẹ́ àṣàmú, láti kékeré ni wọ́n ti ńjẹ ẹnu ṣámú-ṣámú lọ. Alubàtá àgbà lọ́la máa bẹ̀rẹ̀ síí lu kúdi lónǐ. Kúdi ni ìlù Bàtá kékeré fún àwọn ọmọde.
Gbogbo ohun tí a fi ṣe ìlú Bàtá ni ó wá láti ara igi tàbí ara ẹran. Síse ìlù Bàtá àti àwọn ìlù ilẹ̀ Yorùbá ìyókùn gba ẹ̀kọ́ àti ìfarabalẹ̀.
Ẹ gbọ́ ìró ìlù Bàtá níbí. A ri awon kana, ti won lu bata níbí.
Ẹ wo àwọn alubàtá nínú fídíò yí..