Ṣákárà

Àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ràn ìlù ṣákárà púpọ̀. Sísè rẹ̀ kò nira rárá tí a bá fi wé àwọn ìlù ìyókùn. Bákannáà, ìlù ṣákárà kò wúwo láti gbé lọ́wọ́ àti láti lù. Ṣùgbọ́n, ẹ má fi ojú di ṣákárà rárá o, kíkéré l´abẹ́rẹ́ kéré, kìí ṣe mímì fún adìrẹ, bí ṣákárà ṣe kéré tó, o leè múu yín jùrù!

Ìró ìlù ṣákárà yantanran, ó jọ̀lọ̀, ó sì dùn létí púpọ̀. Èyí kún ìdí tí àwọn ọ̀dọ́ ṣe fẹ́ràn ṣákárà púpọ. A lèe lu ṣákárà lóhun nìkan tàbí kí á fi kún àkójọpọ̀ ìlù nínú orin òde òní.

Ẹ wo àwọn ẹgbẹ́ oníṣákárà níbí. Ẹ pe àkíyèsí sí bí àwọn okùrin wọ̀nyí ṣe ńfi ìlù ṣákárà dárà, kọ orin, àti jó sí ìlù amóríyá yǐ pẹ̀lú ìrọ̀rùn.

Jákè-jádò ilẹ̀ Yorùbá ni a ti mọ nípa ìlu ṣákárà. Ṣùgbọ́n, ìlù ṣákárà jẹ́ ìlù tí àwọn Ẹ̀gbá fẹ́ràn púpọ̀. Orin àfẹ̀sọ̀jó kan wà tí a mọ̀ sí ‘orin ṣákárà’ - ìlù ṣákárà ni ojú ìlu tí wọn ńlù sí orin yǐ, ìdí nìyí tí a fi pe orin yǐ ní ‘ṣákárà’. Orin ṣákárà tura, ó mìnìjọ̀jọ̀, ó rọrùn láti jo. Ẹni tí kò mọ̀ọ́ jó rárá, le máa mì lẹ̀gbẹ̀ sí orin ṣákárà. Orin àtijọ́ ni orin ṣákárà, ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀dọ́ ti bẹ̀rẹ̀ síí rí ọgbọ́n, òye, ẹwà èdè àti adùn tí ó wà nínú orin ṣákárà.

Onílù ṣákárà ìṣẹ̀ǹbáyé le fi ìlù ṣákárà ki oríkì, pa òwe àti fi sọ àsàyàn ọ̀rọ̀ láti mú kí ìró ìlu àfẹ̀sọ̀jó yǐ lárinrin.