Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀

Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ko jọ àwọn ìlù ìyókùn. Agbè àti okùn (láti ara awọ ẹran) tí a sín ìlẹ̀kẹ̀ tàbí owó ẹyọ mọ́ lára ni wọ́n fi ṣe ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ìró ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ yàtọ̀ gédégbé, ówẹ́ léti, a sì máa dánilárayá. Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ dùúnjó lóhun nìkan, ṣùgbọ́n a tún le lòó nínú àkójọpọ̀ àwọn ìlù míràn láti mú kí ìró orin wa ní ìlẹ̀ Yorùbá lóyin létí.

Oníṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ máa ńfi ọwọ́ gbá ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ tàbí kí ó máa yíi po tàbí kí ó máa gbọ̀ọ́n rìrì láti mú ìró ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ jáde. Tí eré bá wọ’ra tán, oníṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ leè ju ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ sókè, kí ò tún tẹ́wọ́ gbàá láti dá àwọn olùwòran lára yá.

Nítorípé ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ kò nira láti lò, tọkùrin, tobìrin ló le fi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ dárà.

Àwọn eléré kan wà tí a mọ̀ sí oníṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ àti aro. Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ àti agogo tí a ńpè ní aro ni àwọn eléré yǐ máa ńlò láti fi dá àwọn ènìyàn lára yá. Nígbà míràn wọ́n le ṣeré papọ̀ pẹ̀lú àwọn onílù dùndún. A le rí àwọn oníṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ àti aro ni ibi ayẹyẹ bíi ìgbéyàwó, ìṣílé, ìkómọjáde....., pàápàá jùlọ ní àwọn ìlú kékere gbogbo káàkiri ilẹ̀ Yorùbá

Ẹ wo àwọn oníṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ àti aro níbí.

Ẹ tún wo àwọn obìnrin oníṣẹ̀kẹ̀rẹ̀.