Dùndún

Ìlù dùndún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ìlù tí a mọ̀ jùlọ ní ilẹ̀ Yorùbá. A le lo ìlù dùndún lóhun nìkan tàbí pẹ̀lú àwọn ìlù míràn láti mú kí ìró ìlù lárinrin létí. Ní ayé àtijọ́, àwọn onílù dùndún máa ńfi ìlù yǐ ki àwọn ọba àti àwọn ìjòyè ìlú lójoojúmọ́. Fífi ìlù ki àwọn ọba àti àwọn ìjòyè sì wà ní ilẹ̀ Yorùbá lónǐ.

Àṣà Yorùbá jẹ́ àṣà tí ó jilẹ̀ nínú ìlò èdè àti fífi ohùn dárà. Gbogbo ọmọ Yorùbá ní ìbámu pẹ̀lú ilé tí a ti bí wọn ni ó ní ìfohùn-dárà àpọ́nlé tí a mọ̀ sí oríkì. Bí a ṣe ńki ọmọ Ẹ̀gbá yàtọ̀ sí ti ọmọ Ọ̀yọ́, bí a ṣe ńki Ìjẹ̀ṣá yàtọ̀ sí Òmù-àrán - èyí ló mú wa sọ wípé, ó ní bí kálukú ṣe ńṣe tirẹ ní’lé baba tó bí wọn lọ́mọ. A má a ńfi ìlù dùndún ki oríkì púpọ̀, a máa ńfi ìlu dùndún pa òwe, àti fi sọ àṣàyàn ọ̀rọ̀. Èyí fi adùn sí ìró ìlu àti orin Yorùbá, ó dá ìlù wa yàtọ̀ gédégbé sí àfigi-gbági lásán.

Àwọn tí ó ti dàgbà ní ó máa ńlu ìlu dùndún. Ṣùgbọ́n ní ìdílé onílù, ní ibi tí ó ti jẹ́ wípé iṣẹ́ wọn ni ìlù lúlù, ẹ̀kọ́ nípa ìlu lúlù bẹ̀rẹ̀ láti kékeré. Àwọn àgbàlagbà á ṣe ìlù àti ọ̀pá ìlù kékeré fún àwọn ọmọdé, wọ́n a fún wọn láyè láti tẹ̀lé wọn lọ sí ibi ayẹyẹ tàbí kí wọn máa fi ìlù wọn ṣeré kiri. Fífi ìlù kọ́ àwọn ọmọdé báyǐ máa jẹ́ kí wọn tètè mọ ìlù’úlù. Àwọn ọmọ onílù kìí ṣe aṣáájú ní ìgbà tí wọn bá ńkọ́ ìlù lọ́wọ́. Àwọn agba onílù ṣe báyǐ láti ríi dájú wípé ìró ìlù tí ó yantanran ni wọ́n ńgbe jáde sí etí àwọn olùgbọ́ ní gbogbo ìgbà.

Àwọn onílù dùndún jẹ́ onílù nítorípé a bí wọn ní ìdílé onílù dùndún. Èyí jásí wípé, Àyádìran jẹ́ onílù nítorípé bàbá àti baba-baba rẹ̀ jẹ onílù dùndún.

Ní òde òní, a le rí ìlù dùndún ní ibi ayẹyẹ ìgbeyàwó, ìkómọjáde, ìṣílé, ìkọ́wěgboyè, àti bẹ́è-bẹ́ẹ̀ lọ.

Ẹ wo onílù dùndún ni àkọ́kọ́ ati èkejì.

Ẹ tún wo àkójọpọ̀ àwọn onílù dùndún níbí.